TRENDING

Wednesday, 16 September 2020

IROYIN YORUBA: IMRDF- Ajo Omo Ijesa T'ohun Npe Fun Wiwa Kusa Lona Toto Se Ipade Pelu Awon Lobaloba, Adari Esin, Iyaloja/Babaloja ati awon Odo Ijoba Ibile Ila Oorun Atakumosa Ni Ilu Iperindo
 

Aworan awon kabiyesi ati awon omo igbimo IMRDF
Mohunmaworan (Vide) awon oba ati awon ti o kopa ninu eto apero naa


Awon omo egbe aladani (NGO) ti won nto awon omo Ijesa sona lori anfaani to ro mo wiwa kusa lona to to ati ti o ye (Ijesa Mineral Resources Development Forum IMRDF), ti se ipade pelu awon lobaloba, ijoye, awon oludari ati asoju esin Kirisitieni ati Musulumi pelu awon odo ti won ngbe ni agbegbe Ila Oorun Atakumosa (Atakumosa East local Government). Ojo Isegun (Tuesday) 15/9/2020 ni ipade naa waye ni inu ile ise ijoba ibile ti o wa ni ilu Iperindo.
Asiwaju Yinka Fasuyi ni o ko awon omo igbimo naa sodi lo si ipade pataki yii.


Ninu ipade ajoro ati ifikuluku naa ni awon omo igbimo ti se alaye lori orisirisi ona ati igbekale igbalode ti o le mu akoyawo wa ninu iwakusa ati lati je ki kusa wiwa wa ni ibamu pelu bi won se nse ni aye ode oni, lojuna ati mu ki igbe aye iderun ba awon eeyan ilu tabi igberiko ti won ti nwa kusa laisi ipalara.


Mohunmaworan (Video); te aworan yi loju lati wo o

Mohunmaworan (Video); te aworan yi loju lati wo o

Mohunmaworan (Video); te aworan yi loju lati wo o

Mohunmaworan (Video); te aworan yi loju lati wo o


Ninu ifukuluku ni alaye kikun  ti waye lat enu awon omowe, ojogbon ati akosemose ti won je omo  Ajo IMRDF. 


Asiwaju Fasuyi se alaye ni ekunrere lori bi anfaani ati erenje to ba ma jade lati ara kusa wiwa ti ile ise Segilola ti o kale si agbegbe Iperindo. Odo ati Mogbara se le wulo fun teru tomo fun igba pipe. Asiwaju ro awon Oba lati ma gba owo aito lowo awon awakusa tabi ile ise ati lat ma ta ile ijesa fun awon ajoji naa. O gba awon asoju ilu ni imonran lati ma ya won nile (lease) dipo tita ile leyin titopinpin wipe iwe ase ati wakusa (mining/exploration license) wa ni ona ti o ba ofin mu.


Mohunmaworan (Video); te aworan yi loju lati wo o

Mohunmaworan (Video); te aworan yi loju lati wo o

Mohunmaworan (Video); te aworan yi loju lati wo o


Koko oro ti o suyo ninu ipade yi ni wipe awon olugbe ilu ati igberiko gbodo yago fun awon eroja oloro ti awon awakusa nlo ti o le ba ogbin oko ati omi ti o nsan je fun ilera ara ilu ati ile ti won fi nda oko.


Bakan naa ni oro jade lori eto awon ara ilu lati odo awon awakusa bii ile iwosan (medical centres), ipese ise fun awon odo (youth employment), iranlowo fun eto eko awon odo (scholarship) ati ipese awon ohun amuludun (social amenities) si igberiko ati agbegbe ti awon nkan alumoni ile yi wa.Awon Oba mokanlelogun (21) ni won peju fun ipade naa; Oba Alex Kujembola, Onitaapa of Itapa ni o soju Ogboni ti ilu Ipole gegebi alaga lobaloba pelu awon oba wonyi; Oba Adeyemi Adebowale -Alamo ti Ayegbaju, Oba Micheal Adebanjo - Alajido ti Ajido, Oba Joseph Ekemode - Ajemba ti Ijemba, Oba Samuel Adelola - Akoromoja ti Ikoromoja, Oba Adesoji Adebayo - Apanla ti Ipanla, Oba Kehinde Aladejobi -Alapede ti Ipaede, Oba Adedoja Olanibi - Awikun ti Iwikun, Oba Bashiru Onigbogi - Alawooda ti Owooda, Oba Kehinde Teniola - Alayetoro ti Ayetoro, Oba Ademola Oginni - Olokeodo ti Oke-Odo, Oba Stephen Komolafe - Onitemidayo ti Temidayo, Oba Bamidele Adeyeye - Olumulu ti Imogbara.


Oba Adesuyi Adedapo - Likure ti Odogbo, Oba Olalekan Awotunde - Olowode ti Owode, Oba Adewusi Adewale - Eleyigun ti Eyigun, Oba Ezikiel Fagbemi - Olomiodo ti Omi-Odo, Oba Ilesanmi Abiola - onikajola Bowaje, Oba Adekanmi Ajijala - Olutedo ti Oloruntedo, Oba Aluko Oluwaloni - Olusogo ti Olorunsogo ati Oba Aderibigbe Samson - Alayeni ti Ayeni naa ko gbeyin ninu ipade apero yii.

Awon omo ajo IMRDF ti won pelu won alaga Asiwaju Yinka Fasuyi  ni Mr. Supo Shadiya, Prof. Idowu Olayinka, Dr. Adigun Adewoye, Prof. Gbenga Okunlola, Hon. Justice Dotun Onibokun, Arc. Ayo Osunloye, Mrs. Dupe Ajayi Gbadebo, Alh. Lateef Bakare, Mr. Ezikiel Ogunjuyigbe, Mr. Wale Idowu, Mr. Dosu Babatunde, Amb. Ayo Olukanni ati Dr. Olusegun Ojo.


Bakanaa ni awon odo omo Ijesa (Ijesa Youth Forum) wa ni ipade naa.
Aworan lati owo ayaworan/oniroyin Oladimeji Lasore fun ile ise Kakakioodua (+2347035105413)


No comments:

Post a Comment